Luke 9:7-18

7 aHerodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú; 8Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. 9 bHerodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí: ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.

Jesu bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn

10 cNígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. 11 dNígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.

12Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”

13 eṢùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.”
14Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn.

Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.”
15Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó. 16 fNígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn. 17Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù.

Peteru pe Jesu ní ọmọ Ọlọ́run

18 g hÓ sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”

Copyright information for YorBMYO